Business

Olumo Rock - One Of Nigeria's Natural Wonders

World News

A Yoruba Perspective


From The BBC

Lẹ́yìn tí BBC pariwo iléẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ń kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ lábẹ́ igi, ìjọba Kwara ṣe àtúnṣe
Ileẹkọ miran ni ayika wọn pẹlu tun n ke si ijọba fun iranlọwọ gẹgẹ bi eyi ti wọn ṣe ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ Kankan.


Ìpínlẹ̀ Eko, Ondo, Anambra kéde àlàkalẹ̀ lóri pínpín oúnjẹ ọ̀fẹ́ lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ ìtẹra-ẹni-pa tó wáyé
Lara awọn alakalẹ ilana tijọba ipinlẹ Eko gbe kalẹ ni pe ẹnikẹni tabi ajọ yoowu to ba fẹẹ gbe eto ti awọn eeyan ti yoo kopa nibẹ yoo le ni 250 gbọdọ lọ fi to awọn ileeṣẹ eleto aabo leti, yala lasiko pọnpọnṣinṣin ọdun yii tabi lẹyin ọdun.


Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá Nàìjíríà ṣàbẹ̀wò sí ẹbí Olatunji 'táwọn ọlọ́pàá' ló pokùn so látìmọ́lé n'Ilorin
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, ACP Olumuyiwa Adejobi lo fi ọrọ naa lede loju opo X rẹ.


Àwọn nǹkan mánigbàgbé nípa Gbenga Adeboye Funwontan
Lẹ́yin tó ṣe àìsàn tó niṣe pẹ̀lú kíndìrín ní Gbega Adeboye gba èkuru jẹ lọ́wọ́ ẹbọra jẹ lọ́dún 2003.


Wo ìlèrí tí ìjọba ṣe fún ẹbí àwọn tí wọ́n tẹ̀ pa nibí tí wọ́n ti fẹ́ gba oúnjẹ ọ̀fẹ́ n'Ibadan, Abuja àti Anambra
Igbakeji aarẹ Kashim Shettima, nigba to n ṣapejuwe iṣẹlẹ ọhun gẹgẹ bi ajalu apapọ lorileede, jẹ ko di mimọ pe ijọba apapọ ti paṣẹ fun gbogbo awọn ileeṣẹ ijọba tọrọ kan lati dide iranlọwọ fun awọn mọlẹbi to padanu awọn eeyan wọn.


Olatunji kú sí àhámọ́ ọlọ́pàá ní Kwara, wọ́n ní ṣe ló pokùnso
Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, iya oloogbe naa, Morike Olatunji ṣalaye pe inu ile ni ọmọ oun wa lasiko ti ọkan lara awọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ papọ ti orukọ rẹ n jẹ Jelili pe e lati pade ohun ni opopona Balogun Fulani niluu Ilorin.


Ọkùnrin tí wọ́n dájọ́ ikú fún lórí pé ó jí adìẹ gbé sọ̀rọ̀
Gomina Adeleke ni ki adajọ agba ipinlẹ Osun ṣe atungbeyẹwo ẹjọ naa, lati le jẹ ki orukọ Olowookere wa lara awọn ẹlẹwọn ti yoo ri aanu ijọba gba ki ọdun 2024 too pari.


Ìjì líle Cyclone Chido kọlu Mozambique, èèyàn 94 pàdánù ẹ̀mí wọn
Irufẹ iji lile ọhun ti kọkọ ṣọṣẹ nilẹ Mayote, ko to lọ kulu awọn eeyan Mozambique, Malawi ati Zimbabwe.


Àwọn tó kú níbi tí wọ́n ti ń pín oúnjẹ ọ̀fẹ́ ní Anambra ti di 22
Iṣẹlẹ yii lo n waye lẹyin ọjọ mẹta ti wọn tẹ ọmọ marundinlogoji pa niluu Ibadan.


Awakọ̀ wa ọkọ̀ wọ inú ọjà ọdún Kérésìmesì, èèyàn 200 farapa
Obinrin kan to wa pẹlu ọrẹkunrin rẹ ti wọn wa ninu ọja Keresimesi ọhun to wa ni Magdeburg sọ fawọn akọroyin pe oun di ololufẹ oun lọwọ mu lasiko ti ọkọ naa n sare bọ niwaju awọn.


Àwọn tó kú níbi tí wọ́n ti ń pín oúnjẹ ọ̀fẹ́ ní Anambra ti di 22
Iṣẹlẹ yii lo n waye lẹyin ọjọ mẹta ti wọn tẹ ọmọ marundinlogoji pa niluu Ibadan.


"Ọmọ mẹ́rin ni mo kó lọ sí àpèje Ibadan, mẹ́ta ló bá mi wálé"
Ninu atẹjade ọlọpaa ni wọn ti sọ pe ọmọ marundinlogoji (35) lo ku ninu ajalu naa.


Orílẹ̀èdè Australia ń wá àwọn èèyàn tí yóò jápa wá sọ́dọ̀ wọn
Nibi eto ifilọlẹ fisa tuntun ti Australia ṣe, ti wọn pe ni 'National Innovation Visa', ni wọn ti sọ eyi di mimọ.


Ọlọ́pàá mú afurasí babaláwo méjì tó fẹ́ẹ́ fi òògùn abẹnugọ̀ǹgọ̀ dán ààrẹ wò
Ni apa Guusu ilẹ Africa yii, ọpọ eeyan lo ṣi ni igbagbọ ninu pe ajẹ wa, ati pe wọn le pa awọn.


Ìjàmbá ọkọ̀ pa ọlọ́pàá mẹta àti obìnrin kan l'Ondo
Alukoro Ileeṣẹ ọlọpaa Ondo, Funmilayo Odunlami-Omisanya, lọ sọ iṣẹlẹ yii di mimọ ninu atejade to fi lede.


Wo àwọn ọ̀nà tí o lè fi dáàbò bo ọmọ rẹ níbi àpéjọ elérò púpọ̀
Awọn alakalẹ ti a ko jọ yii wa fun awọn to gbe eto kalẹ ati fun awọn ti yoo kopa ninu irufẹ eto bẹẹ, paapaa awọn ti yoo ko ọmọ wọn lọ si irufẹ eto bẹẹ.


Ẹ wo bí ìgbẹ́jọ́ Dele Farotimi ṣe lọ ní Ado-Ekiti lónìí
Agbẹjọro, Dele Farotimi, yọju sile ẹjọ


Ààrẹ Tinubu sọ̀rọ̀ lórí ikú àwọn ọmọdé tó wáyé níbi ayẹyẹ Naomi nìlùú Ibadan
Aarẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu sọrọ lori ajalu to waye niluu Ibadan


Ọ̀rọ̀ taa ni yóò jẹ Owa Obokun tuntun n'Íléṣà dá wàhálà sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ oyè
Awọn ti wọn pe lẹjọ ni Gomina Ademola Adeleke; Obanla ilu Ijesa, Oloye Folorunso Adeniyi, ati awọn afọbajẹ mọkanla; igbimọ ọba alaye nilẹ Ijesa; Kọmiṣanna feto idajọ, to fi mọ Kọmiṣanna fọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ.


Ìjọba FCT gba ilẹ̀ lọ́wọ́ Buhari Foundation, Akume, Okorocha, Melaye àti àwọn mìí nítorí gbèsè
Ilẹ Ajọ Mohammadu Buhari, ilẹ Rochas Okorocha, George Akume, Dino Melaye ati awọn miran wa lara awọn ilẹ ti minisita kede pe awọn ti gba pada.


CBN kéde pé aráàlú kò ní lè gbà ju N100,000 lọ lójúmọ́ lórí POS
Ọjọ Iṣegun, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kejila ọdun 2024, ni CBN fi atẹjade kan sita, ninu eyi ti wọn ti kede igbesẹ yii.


Kókó márùn ún nínú ètò ìṣúná N47.96tn tí Tinubu gbé lọ síwájú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin l'Abuja
Aarẹ Tinubu sọ fawọn aṣofin pe eto iṣuna naa yoo jẹ ki ọwọngogo nnkan lọlẹ lati ida 34% to wa lọ si ida 15% lọdun 2025.


Ipa wo ni ìṣubú Assad yóò ní lórí àwọn ọmọ ogun Russia ní Africa?
Lọdun 2017, ijọba Russia buwọlu iwe adehun kan pẹlu Aarẹ al-Assad eyi to fun Russia lanfaani lati lo ilu Tartus ni Syria lọfẹẹ fun awọn ọmogun ori omi rẹ fun ọdun mọkandinlaadọta.


Kí ló kan iléeṣẹ́ rédíò Agidigbo nípa ìṣẹ̀lẹ̀ tó mú ẹ̀mí àwọn ọmọdé lọ níbi àpèjẹ Olori Naomi?
Ọga agba ẹka igbohun safẹfẹ ileeṣẹ redio naa, Ọgbẹni Olayinka AbdulWahab, lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fita nirọlẹ Ọjọru.


Àwọn tó ṣètò àpèjẹ ọdún tí àwọn ọmọde ti kú n'Ibadan ti wà ní àhámọ́ - Makinde
Ninu atẹjade ti Gomina Makinde fi soju opo aye;ujara ti 'X' rẹ l'Ọjọru, lo ti jẹ ko di mimọ pe iṣẹlẹ ọhun kọ oun lominu pupọ, ti ko si dun mọ oun ninu.


Gómínà Adeleke pàṣẹ ìtúsílẹ̀ ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n dájọ́ ikú fún nítorí pé ó jí adìyẹ̀
Olowookere ni Onidajọ Jide Faola ti ile-ẹjọ giga to wa niluu Okuku, ipinlẹ Osun paṣẹ pe ki wọn lọ yẹgi fun lori ẹsun wi pe o ji adiẹ ati ẹyin gbe ninu oko adiẹ lọdun mẹwaa sẹyin.


Ní ìlú yìí, àwọn òǹtàjà gbàgbọ́ pé kámẹ́rà CCTV inú ṣọ́ọ̀bù wọn le ṣekú pa wọ́n
Awọn olokowo lọkunrin naa sọ pe bawọn ba fi kamẹra sibi ti ijọba n fẹ, iku ti yoo pa awọn lawọn dan wo yẹn. Wọn ni awọn awọn Al-Shabab to n yinbọn kiri yoo yinbọn pa awọn danu ni. B'awọn ko ba si fi kamẹra naa sibẹ, ọlọpaa yoo mu awọn.


Ìdí tí owó àlùbọ́sà fi wọ́n lọ́dún 2024 ju àwọn ọdún yòókù lọ
Kolonka ni igba ti owo alubọsa ti lọ soke, to si tun ti wa silẹ laarin ọja kaakiri orileede Naijiria lọdun 2024 ti a wa yii.


'N5,000 tí wọ́n ṣèlérí ni mo fẹ́ lọ gbà níbi àpèjẹ tí wọ́n ti tẹ ọmọ mi mọ́lẹ̀'
Ọkan lara obi awọn ọmọ ti ori ko yọ lọwọ iku ojiji nibi apejẹ ti Olori Ooni Ile-Ife tẹlẹ, Naomi Ogunwusi ṣe niluu Ibadan, ti ṣe alaye bi ọgọọrọ ero ṣe tẹ awọn ọmọ rẹ meji mọlẹ lasiko ijijadu fun ẹbun ọdun.


Ààfin Ooni sọ̀rọ̀ lórí àpèjẹ Olori Naomi níbi tí ọ̀pọ̀ ọmọdé ti kú n'Ibadan
Ninu atẹjade kan ti adari eto iroyin fun aafin Ooni, Otunba Moses Olafare, fi sita ni aafin Ooni Ile Ife, Enitan Ogunwusi, Ojaja Kẹta ti sọ pe ọgbẹ ọkan ni iṣẹlẹ yii jẹ fawọn naa.


Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá sọ pàtó iye ọmọ tó kú níbi àpèjẹ́ Naomi Ogunwusi n'Ibadan
Ileeṣẹ ọlọpaa sọrọ lori iṣẹlẹ to waye nibi apejẹ opin ọdun to mu ẹmi lọ niluu Ibadan


Òkú sùn níbi fàájì òpin ọdún tí Olori Naomi Ogunwusi ṣe f'áwọn ọmọdé nílùú Ibadan
Awọn ọmọde ku nibi ayẹyẹ opin ọdun ti Olori Naomi ṣe niluu Ibadan


'Àsàsí ló mú mi pa ọmọ mi lọ́mọ́ oṣù kan ààbọ̀, kìí ṣe pé mo fẹ́ fi ṣe ètùtù ọlà'
Ọwọ ọlọpaa tẹ baba ọmọ ti wọn furasi pe, oun lo dumbu ọmọ naa


Wo ìye tí o gbọ́dọ̀ ní tí o bá fẹ́ rìnrìnàjò tàbí lọ kẹ́kọ̀ọ́ ní UK láti ọdún 2025
O ti tojọ mẹta ti ilu naa ti n gbe igbesẹ ti ko ni i jẹ ki awọn arinrinajo to n wọle, ṣe akoba fun ile gbigbe ati ọrọ aje wọn.


Àwọn ọmọ Nàìjíríà márùn ún tó ti gbàmì ẹ̀yẹ agbábọ́ọ̀lù tó pegedé jùlọ l'Afirika ṣaájú Lookman
Ni bayii, igba meje ọtọtọ ni orilẹede Naijiria ti gba ami ẹyẹ ere bọọlu yii lati igba to ti bẹrẹ.


Ọwọ́ EFCC tẹ ọmọ ilẹ̀ òkèèrè 158 tó ń kọ́ àwọn ọmọ Naijiria ní 'Yahoo-yahoo'
EFCC fi kun un pe ilana okowo igbalode ti wọn n pe ni Crytocurrency, ni awọn onijibiti yii tun maa n lo, bi wọn ko ba purọ ifẹ.


Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn tó fi èpè ránṣẹ́ sí Ààrẹ Tinubu àti ọ̀gá àgbà ọlọpàá dèrò àtìmọ́lé
Ogunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2024 yii ni wahala naa bẹrẹ fun Olamide lasiko iwọde iranti EndSARS.


Ecowas fẹ́ la ọ̀nà láti Ivory Coast sí Naijiria
Ajọ ECOWAS n gbero lati la ọna ti yoo so orilẹ-ede marun-un pọ


Àwọn alákatakítí ẹ̀sìn jí mi gbé fún ọ̀sẹ̀ méjì, wọ́n ní dandan ni kí n darapọ̀ mọ́ àwọn
Pẹlu nnkan ti oju rẹ ri ni agọ wọn, o ni oun gbagbọ pe lati kekere ni wọn ti n kọ wọn bi wọn ṣe n wu iwa igbesunmọ ti wọn si n kọ wọn bi wọn yoo ṣe so ado oloro mọ ara wọn.


Wo bí ìgbẹ́jọ́ ọkùnrin tó ní kí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà yọ Tinubu nípò ṣe lọ l'Abuja
Ọgbẹni Ambrose Owuru pe ẹjọ wi pe Tinubu ko koju oṣuwọn lati jẹ aarẹ Naijiria tori ẹsun gbigbe oogun oloro ti wọn fi kan an lorilẹede Amẹrika.


Learning Never Stops

The Line Between Disorder And Order Lies In Logistics